Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 3:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, kí o sì gba gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sí ọkàn rẹ.

11. Lọ nísinsìnyìí sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ tó wà ní ìgbèkùn. Sọ fún wọn pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn kò gbọ́.”

12. Nígbà náà ni Ẹ̀mí gbé mi sókè, mo sì gbọ́ ohùn ìró ńlá lẹ́yìn mi-tó sọ pé, kí a gbé ògo Olúwa ga láti ibùgbé rẹ̀ wá!

13. Bẹ́ẹ̀ ni mo tún gbọ́ ariwo ìyẹ́ apá àti kẹ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà pẹ̀lú ariwo tó dàbí àrá ńlá.

14. Ẹ̀mí náà sì gbé mi sókè, ó sì mú mi lọ, mo lọ pẹ̀lú ọkàn kíkorò àti ìbínú nínú ẹ̀mí mi, pẹ̀lú ọwọ́ líle Olúwa ni ara mi.

15. Nígbà náà ni mo lọ sí etí odò Kébárì níbi tí àwọn ìgbèkùn ń gbé ni Teli-Ábíbì. Níbẹ̀ níbi tí wọ́n ń gbé, mo jókòó láàrin wọn pẹ̀lú ìyànu, fún ọjọ́ méje.

16. Lẹ́yìn ọjọ́ méje, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

17. “Ọmọ ènìyàn, mo ti fi ọ́ ṣe òlùṣọ́ fún ìle Ísírẹ́lì; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, fún wọn ní ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 3