Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 28:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,ọkàn rẹ gbé sókèNitorí ọrọ̀ rẹ.

6. “ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run

7. Èmi yóò mú kí àwọn àjòjì dìde sí ọ,ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀ èdè;wọn yóò yọ idà wọn sí ọẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹwọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.

8. Wọn yóò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ wá sínú ihòìwọ yóò sì kú ikú gbígbónáàwọn tí a pa ní àárin òkun.

9. Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́

10. Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlàní ọwọ́ àwọn àjòjìÈmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”

11. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:

12. “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tírè kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹrẹ ìjẹ́pípé náào kún fún ọgbọ́n,o sì pé ní ẹwà

13. Ìwọ ti wà ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run;onírúurú òkúta iyebíye ni ìbora rẹ;sárídù, tópásì àti díámọ́ndì, bérílì oníkì,àti jásípérì, sáfírè, émérálídìàti káríbúnkílì, àti wúràìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dàláti ara wúrà,ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.

14. A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,torí èyí ni mo fi yàn ọ́.Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;ìwọ rìn ni àárin òkúta amúbína,

15. Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹláti ọjọ́ tí a ti dá ọtítí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.

16. Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹìwọ kún fún ìwà ipá;ìwọ sì dẹ́sẹ̀Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nùbí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.Èmi sì pa ọ run,ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárin òkúta amúbínà

17. Ọkàn rẹ gbéraganítorí ẹwà rẹ.Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́nítorí dídára rẹ.Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;mo sọ ọ di awò ojú níwájú àwọn ọba.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 28