Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 28:10-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlàní ọwọ́ àwọn àjòjìÈmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”

11. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:

12. “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tírè kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹrẹ ìjẹ́pípé náào kún fún ọgbọ́n,o sì pé ní ẹwà

13. Ìwọ ti wà ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run;onírúurú òkúta iyebíye ni ìbora rẹ;sárídù, tópásì àti díámọ́ndì, bérílì oníkì,àti jásípérì, sáfírè, émérálídìàti káríbúnkílì, àti wúràìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dàláti ara wúrà,ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.

14. A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,torí èyí ni mo fi yàn ọ́.Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;ìwọ rìn ni àárin òkúta amúbína,

15. Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹláti ọjọ́ tí a ti dá ọtítí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.

16. Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹìwọ kún fún ìwà ipá;ìwọ sì dẹ́sẹ̀Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nùbí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.Èmi sì pa ọ run,ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárin òkúta amúbínà

17. Ọkàn rẹ gbéraganítorí ẹwà rẹ.Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́nítorí dídára rẹ.Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;mo sọ ọ di awò ojú níwájú àwọn ọba.

18. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìsòótọ́ rẹìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá látiinú rẹ, yóò sì jó ọ run,èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.

19. Gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó mọ̀ ọ́ní ẹnu ń yà sí ọ;ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rùìwọ kì yóò sì sí mọ́ láéláé.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 28