Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 24:13-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. “ ‘Nísìn yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èèrí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.

14. “ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é. Èmi kì yóò pada sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà; gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”

15. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá pé:

16. “Ọmọ ènìyàn, kíyèsí i, mo mú ìfẹ́ ojú rẹ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, nípa lílù kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sunkún, bẹ́ẹ̀ ni omijé ojú rẹ kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀.

17. Má ṣe sunkún, má ṣe gbààwẹ̀ fún òkú. Wé ọ̀já sí orí rẹ, sì bọ bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ: má ṣe bo ètè ìsàlẹ̀ rẹ, ma ṣe jẹ oúnjẹ tí àwọn tí ń sọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.”

18. Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn ní òwúrọ̀, ní àṣálẹ́ ìyàwó mi sì kú. Ní òwúrọ́ ọjọ́ kejì, mo ṣe bí a ti pàsẹ fún mi.

19. Lẹ́yìn náà àwọn ènìyàn bi mí léèrè pé, “Ṣe o kò ni sọ fún wa ohun ti nǹkan wọ̀nyí ní láti ṣe pẹ̀lú wa?”

20. Mo sọ báyìí fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

21. Sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, èmi yóò sọ ibi mímọ́ mi di ibi àìmọ́ títayọ agbára yín, ìfẹ́ ojú yín, ìkáànú yín, àti ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin tí ẹ̀yin fi sílẹ̀ sẹ́yìn yóò ṣubú nípa idà.

22. Ẹyin yóò sì ṣe bí mo ti ṣe. Ẹ̀yin kì yóò bo ìsàlẹ̀ ojú yín tàbí jẹ oúnjẹ ti àwọn tí ń sọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.

23. Ẹ̀yin yóò fi àwọn ọ̀já wé àwọn orí i yín àti àwọn bàtà ni ẹsẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yóò sọ̀fọ̀ tàbí sunkún, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ṣòfò dànù nítorí àwọn àìṣedédé yín, ẹ̀yin yóò sì máa kérora láàrin ara yín.

24. Ísíkẹ́ẹ̀lì yóò jẹ àmì fún un yín; ẹ̀yin yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe. Nígbà tí èyí bá sẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run.’

25. “Pẹ̀lúpẹ̀lù ìwọ, Ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé, ní ọjọ́ náà, nígbà ti mo bá gba agbára wọn, ayọ̀ wọn àti ògo wọn, ìfẹ́ ojú wọn, ohun tí wọn gbé ọkàn wọn lé, àti àwọn ọmọ ọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ obìnrin wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn,

26. ní ọjọ́ náà ẹni tí ó bá sálà yóò tọ̀ ọ́ wá láti sọ ìròyìn náà fún ọ

27. Ní ọjọ́ náà ẹnu rẹ yóò sì sí; ìwọ yóò sọ̀rọ̀, ìwọ kì yóò sì yadi mọ́. Báyìí ìwọ yóò jẹ́ àmì fún wọn; wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ní Olúwa.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 24