Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 20:5-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. kí ó sọ fún wọn pé: ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Ní ọjọ tí mo yàn Ísírẹ́lì, mo gbé ọwọ́ mi ṣokè nínú ẹ̀jẹ́ sí àwọn ọmọ ilé Jákọ́bù, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Éjíbítì, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

6. Ní ọjọ́ náà mo lọ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn pé ń ó mú wọn kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn ilẹ̀ yòókù.

7. Mo sì sọ fún wọn pé, “Kí ẹ̀ni kọ̀ọ̀kan yín mú àwọn àwòrán ìríra ti ẹ gbé ṣíwájú yín kúrò, kí ẹ sì má bára yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìsà Éjíbítì, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

8. “ ‘Ṣùgbọ́n wọn sọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́ràn, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojú kọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Éjíbítì sílẹ̀, torí náà mo sọ pé ń ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, ń ó sì jẹ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Éjíbítì.

9. Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè tí wọn ń gbé láàrin wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Ísírẹ́lì nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Éjíbítì.

10. Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Éjíbítì mo sì mú wọn wá sínú ihà.

11. Mo sì fún wọn ni òfin mi, mo sì fi àwọn òfin mi hàn wọ́n; nítori pé ẹni tó bá ṣe wọ́n yóò yè nípa wọn.

12. Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí àmì láàrin àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.

13. “ ‘Síbẹ̀; ilé Ísírẹ́lì sọ̀tẹ̀ sí mí nínú ihà. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀-bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè è nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé ń ó tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, ń ó sì pa wọ́n run nínú ihà.

14. Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè tí mo kó wọn jáde lójú wọn.

15. Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn nínú ihà pé ń kò ní i mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn ilẹ̀ yòókù.

16. Nítorí pé wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àsẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn.

17. Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú ihà.

18. Ṣùgbọ́n mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú ihà pé, “Ẹ má ṣe rìn ní ìlànà àwọn baba yín tàbí kí ẹ pa òfin wọn mọ́ tàbí kí ẹ bara yín jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà wọn.

19. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ó sì pa òfin mi mọ́.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 20