Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 18:12-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ó ni àwọn talákà àti aláìní lára,ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí,o gbójú sókè sí òrìṣà,ó sì ń ṣe ohun ìríra.

13. Ó ń fowó ya ni pẹ̀lú èlé ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù.Ǹjẹ́ irú ọkunrin yìí wa le è yè bí? Kò lè wá láàyè! Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀.

14. “Bí ọkùnrin yìí bá bímọ, tó sì rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti baba rẹ ń ṣẹ̀ yìí, tó sì bẹ̀rù, ti kò ṣe bẹ́ẹ̀:

15. “Tí kò jẹun lójúbọ lórí òkè gígatàbí kò gbójú sókè sí àwọnòrìṣà ilé Ísírẹ́lì, tí kò sì báiyàwó aládùúgbò rẹ̀ jẹ́

16. tí kò ni ẹnikẹ́ni lára,tí kò hùwà ibití kò gba èlé tàbí kò fipá jalèṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ,tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò.

17. Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù,ó ń pa òfin mi mọ́,ó sì ń tẹ̀lé àwọn àsẹ mi.Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè!

18. Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

19. “Síbẹ̀, ẹ tún ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyè sí ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè.

20. Ọkàn tí ó bá sẹ̀ ní yóò kú. Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní i ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀. Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburu náà la ó kà síi lọ́rùn.

21. “Ṣùgbọ́n bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó ti dá, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àsẹ mi mọ́, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, nítòótọ́ ni yóò yè, kò sì ní kú.

22. A kò sì ní rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó ti dá tẹ́lẹ̀ láti kàá sí lọ́rùn nítorí tí ìwà òdodo rẹ tó fihàn, yóò yè

23. Ǹjẹ́ se mo ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní Olúwa wí, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ tó sì yè?

24. “Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́sẹ̀, tó sì tún n ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí? A kò ni i rántí ọ̀kan kan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 18