Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hágáì 2:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje, ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípaṣẹ̀ wòlíì Hágáì wí pé:

2. “Sọ fún Sérúbábélì ọmọ Séítélì, olórí Júdà, àti Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn yòókù. Béèrè lọ́wọ́ wọn pé,

3. ‘Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín?

4. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Sérúbábélì,’ ni Olúwa wí. ‘Múra gírí, ìwọ Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà. Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà;’ ni Olúwa wí, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín;’ ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

5. ‘Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Éjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.’

6. “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

7. Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀ èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀ èdè yóò fà sí Tẹ́ḿpìlì yìí, Èmi yóò sì kùn ilé yìí pẹ̀lu ògo;’ ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

8. ‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

9. ‘Ògo ìkẹyìn àwọn ọmọ-ogun ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ;’ ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí: ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni’, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.”

10. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án ní ọdún kejì Dáríúsì, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Hágáì wá pé:

11. “Báyìí ni Olúwa alágbára wí: ‘Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé:

12. Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan Búrẹ́dì tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’ ”Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”

13. Nígbà náà ni Hágáì wí pé, “Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nipa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọkan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́?”Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́.”

14. Nígbà náà ni Hágáì dáhùn ó sì wí pé, “ ‘Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’ ni Olúwa wí. ‘Bẹ́ẹ̀ sì ni olukuluku iṣẹ́ ọwọ́ wọn; èyí tí wọ́n sì fi rúbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.

15. “ ‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsí bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹ́ḿpìlì Olúwa.

16. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìlé ogún, mẹ́wàá péré ni. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni.

17. Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdú àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jà; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Hágáì 2