Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hábákúkù 2:9-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga,kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!

10. Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹnípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mi rẹ

11. Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.

12. “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú,tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?

13. Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pélàálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún inákí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún aṣán?

14. Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,bí omi ṣe bo òkun.

15. “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,tí ó sì fí ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòòhò wọn

16. Ìtì jú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lúkí ìhòòhò rẹ kí ó lè hàn,aago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ,ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.

17. Nítorí ìwà-ipá tí ó tí hù sí Lébánónì yóò bò ọ́,àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́.Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

18. “Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,ère dídá àti olùkọ́ èké?Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnrarẹ̀ dá;ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.

19. Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘Wá ṣayé?’Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde’Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà?Góòlù àti sílífa ni a fi bò ó yíká;kò sì sí èémí kan nínú rẹ

20. Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹ́ḿpílì mímọ́ rẹ̀;Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé pa rọ́rọ́ níwájú rẹ.”

Ka pipe ipin Hábákúkù 2