orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hábákúkù 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìdáhùn Ọlọ́run Sí Ìráhùn Wòlíì Hábákúkù

1. Èmi yóò dúró lórí ibùṣọ́ mi láti máa wòyeÈmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóreÈmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún nuàti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí;

Ìdáhùn Olúwa

2. Nígbà náà ni Olúwa dáhun pé:“Kọ ìṣípayá náa sílẹ̀kí o sí han ketekete lórí wàláàkí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.

3. Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;yóò máa yára sí ìgbẹ̀yinkí yóò sí sọ èkébí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́”

4. “Kíyèsí, ọkàn rẹ tí ó gbéga;Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,ṣùgbọ́n olododo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.

5. Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí-wáìnì ni ẹ̀tàn,agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmiẹni tí ó sọ ìfá rẹ di gbígbòòrò bí ipò-òkú,ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn,ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

6. “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,“ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i!Tí ó sì ṣọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípaṣẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́ gbà!Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’

7. Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde lójijì?Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò ha jí ni bi?Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.

8. Nítorí ìwọ tí ko orílẹ̀-èdè púpọ̀,àwọn ènìyàn tó kù yóò sì kó ọnítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀Ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá runàti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.

9. “Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga,kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!

10. Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹnípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mi rẹ

11. Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.

12. “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú,tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?

13. Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pélàálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún inákí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún aṣán?

14. Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,bí omi ṣe bo òkun.

15. “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,tí ó sì fí ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòòhò wọn

16. Ìtì jú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lúkí ìhòòhò rẹ kí ó lè hàn,aago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ,ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.

17. Nítorí ìwà-ipá tí ó tí hù sí Lébánónì yóò bò ọ́,àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́.Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

18. “Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,ère dídá àti olùkọ́ èké?Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnrarẹ̀ dá;ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.

19. Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘Wá ṣayé?’Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde’Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà?Góòlù àti sílífa ni a fi bò ó yíká;kò sì sí èémí kan nínú rẹ

20. Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹ́ḿpílì mímọ́ rẹ̀;Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé pa rọ́rọ́ níwájú rẹ.”