Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 9:13-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ẹ́sítà sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.”

14. Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Ṣúṣà, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hámánì kọ́.

15. Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ní Ṣúṣà, Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ ọ wọn lé ìkógún un wọn.

16. Lákókò yìí, àwọn tó kù nínú àwọn Júù tí wọ́n wà ní agbégbé ọba náà tún kó ara wọn jọ láti dáàbò bo ara wọn kí wọn sì sinmi lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn. Wọ́n sì pa ẹgbàá mẹ́tadínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rin (75,000) àwọn tí ó kóòríra wọn ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ọ wọn lé ìkógún un wọn.

17. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì, wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àṣè àti ayọ̀.

18. Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ Kẹẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àṣè àti ayọ̀.

19. Nítorí náà ni àwọn Júù-tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àṣè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn.

20. Módékáì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù jákèjádò àgbáyé ọba Ṣéríṣésì, tí ó wà ní tòòsí àti àwọn tí ó wà ní jìnnà réré,

21. Láti lè máa ṣe àjọyọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù Ádárì ní ọdọọdún

22. Gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀. Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àṣè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní.

23. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe bí Módékáì ti kọ̀wé sí wọn.

24. Nítorí Hámánì ọmọ Hámédátà, aráa Ágágì, ọ̀ta gbogbo àwọn Júù, ti gbérò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di Púrì (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìṣọdahoro àti ìparun wọn.

25. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ẹ́sítà sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hámánì ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí oun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 9