Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 7:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ní oṣù kánùn-ún ọdún keje ọba yìí ni Ẹ́sírà dé sí Jérúsálẹ́mù.

9. Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ láti Bábílónì ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ó sì dé Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ara rẹ̀.

10. Ẹ́sírà ti fi ara rẹ̀ jìn fún kíkọ́ àti pípa òfin Olúwa mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mósè ní Ísírẹ́lì.

11. Èyí ni ẹ̀dà lẹ́ta ti ọba Aritaṣéṣéṣì fún àlùfáà Ẹ́sírà olùkọ́ni, ẹni tó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ òfin àti ìlànà Olúwa fún Ísírẹ́lì:

12. Aritaṣéṣéṣì, ọba àwọn ọba,Sí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ni òfin Ọlọ́run ọ̀run:Àlàáfíà.

13. Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkòóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jérúsálẹ́mù lè tẹ̀lé ọ lọ.

14. Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèjè rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

15. Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jérúsálẹ́mù,

16. pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Bábílónì àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run wọn ní Jérúsálẹ́mù.

17. Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ (ọkà), àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ ní Jérúsálẹ́mù.

18. Ìwọ àti àwọn Júù arákùnrin rẹ lè fi èyí tó kù fàdákà àti wúrà ṣe ohunkóhun tí ó bá dára lójú yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yín.

19. Kó gbogbo ohun èlò tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ fún Ọlọ́run Jérúsálẹ́mù fún ìsìn nínú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ.

20. Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba.

21. Èmi, ọba Aritaṣéṣéṣì, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Yúfúrátè láìrójú láti pèṣè ohunkóhun tí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín

22. tó ọgọ́run kan talẹ́ntì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òṣùwọ̀n jéró, ọgọ́rùn-ún gálọ́ọ̀nù wáìnì, ọgọ́rùn-ún gálọ́ọ̀nù òróró olífì, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 7