Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 7:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ní ọdún keje ọba Aritaṣéṣéṣì díẹ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì náà gòkè wá sí Jérúsálẹ́mù.

8. Ní oṣù kánùn-ún ọdún keje ọba yìí ni Ẹ́sírà dé sí Jérúsálẹ́mù.

9. Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ láti Bábílónì ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ó sì dé Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ara rẹ̀.

10. Ẹ́sírà ti fi ara rẹ̀ jìn fún kíkọ́ àti pípa òfin Olúwa mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mósè ní Ísírẹ́lì.

11. Èyí ni ẹ̀dà lẹ́ta ti ọba Aritaṣéṣéṣì fún àlùfáà Ẹ́sírà olùkọ́ni, ẹni tó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ òfin àti ìlànà Olúwa fún Ísírẹ́lì:

12. Aritaṣéṣéṣì, ọba àwọn ọba,Sí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ni òfin Ọlọ́run ọ̀run:Àlàáfíà.

13. Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkòóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jérúsálẹ́mù lè tẹ̀lé ọ lọ.

14. Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèjè rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

15. Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jérúsálẹ́mù,

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 7