Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 6:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a si fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn.

12. Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀ èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹ́ḿpìlì yìí tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù ṣubú.Èmi Dáríúsì n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímú ṣẹ láì yí ohunkóhun padà.

13. Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dáríúsì pa, Táténáì, Baálẹ̀ ti agbégbé Yúfúrátè, àti Ṣétarì-Bóṣénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn pa á mọ́ láì yí ọ̀kan padà.

14. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbààgbà Júù tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hágáì àti wòlíì Ṣekaráyà, ìran Ídò. Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti àwọn àṣẹ Ṣáírúsì, Dáríúsì àti Aritaṣéṣéṣì àwọn ọba Páṣíà pọ̀.

15. A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Ádárì (oṣù kejì) ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dáríúsì.

16. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì—àwọn ìkógun, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀.

17. Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù (100), ọgọ́rùn-ún méjì àgbò (200) àti ọgọ́run mẹ́rin akọ ọ̀dọ́ àgùntàn (400), àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì, obúkọ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

18. Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpínsọ́wọ́ àti àwọn Léfì sì ẹgbẹẹgbẹ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mósè.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 6