Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 10:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Ẹ́sirà ń gbàdúrà tí ó sì ń jẹ́wọ́, ti ó ń sunkún ti ó sì ń gbárayílẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lí ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé pagbo yí i ká. Àwọn náà ń sunkún kíkorò.

2. Nígbà náà ni Ṣékáníáyà ọmọ Jéhíélì, ọ̀kan lára ìran Élámù, sọ fún Ẹ́sírà pé, Àwa ti jẹ́ aláìsọ̀ọ́tọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì láàrin àwọn ènìyàn tí ó wà yí wa ká. Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ náà, ìrètí sì wà fún Ísírẹ́lì

3. Ní sinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a dá májẹ̀mú níwájú Ọlọ́run wa láti lé àwọn obìnrin yìí àti àwọn ọmọ wọn lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn Ẹ́sírà Olúwa mi àti ti àwọn tí ó bẹ̀rù àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa. Ẹ jẹ́ kí a ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin.

4. Dìde, nítorí, ọ̀rọ̀ tìrẹ ni èyí. Gbogbo wà yóò wá pẹ̀lú rẹ, mú ọkàn le kí o sì ṣe é.

5. Nígbà náà ni Ésírà dìde, ó sì fi àwọn aṣíwájú àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Ísírẹ́lì sí abẹ́ ìbúra, láti ṣe ohun tí wọ́n dá lábàá. Wọ́n sì búra.

6. Nígbà náà ni Ẹ́sírà padà sẹ́yìn kúrò níwájú ilé Ọlọ́run, ó sì lọ sí iyàrá Jéhóhánánì ọmọ Élíásíbù. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, kò jẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi, nítorí ó sì ń káàánú fún àìsòótọ́ àwọn ìgbèkùn.

7. Ìkèdè kan jáde lọ jákèjádò Júdà àti Jérúsálẹ́mù fún gbogbo àwọn ìgbèkùn láti péjọ sí Jérúsálẹ́mù.

8. Ẹnikẹ́ni tí ó ba kọ̀ láti jáde wá láàrin ọjọ́ mẹ́ta yóò pàdánù ohun ìní rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu àwọn ìjòyè àti àwọn àgbààgbà, àti pé a ó lé òun fúnraaarẹ̀ jáde kúrò láàrin ìpéjọpọ̀ àwọn ìgbèkùn.

9. Láàrin ọjọ́ mẹ́ta náà, gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà àti Bẹ́ńjámínì tí péjọ sí Jérúsálẹ́mù. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹ́sàn án, gbogbo àwọn ènìyàn jókòó sí ìta gbangba iwájú ilé Ọlọ́run, wọ́n wà nínú ìbànújẹ́ ńlá nítorí ọ̀ran yìí, àti nítorí òjò púpọ̀ tó tì rọ̀.

10. Nígbà náà ni àlùfáà Ẹ́sírà dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe àìsòótọ́, ẹ ti fẹ́ obìnrin àjèjì, ẹ ti dá kún ẹ̀bi Ísírẹ́lì.

11. Nísinsìnyìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrin àwọn ìyàwó àjèjì yín.”

12. Àpéjọpọ̀ ènìyàn náà sì dáhùn lóhùn rara pé: ohun tí ó sọ dára! A gbọdọ̀ ṣe bí o ti wí.

13. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni ó wà ni ibi yìí ṣíbẹ̀ àkókò òjò ni; àwa kò sì lè dúró níta. Yàtọ̀ sí èyí, a kò le è yanjú ọ̀rọ̀ yìí láàrin ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ jọjọ lórí awọn nǹkan wọ̀nyí.

14. Jẹ́ kí àwọn ìjòyè wa ṣojú fún gbogbo ìjọ ènìyàn, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìlú wa tí ó ti fẹ obìnrin àjèjì wá ní àsìkò tí a yàn, pẹ̀lú àwọn àgbààgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ìbínú gíga Ọlọ́run wa lórí ọ̀rọ̀ yìí yóò fi kúrò ní orí wa.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 10