Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 7:9-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “Ní ìgbà tí Fáráò bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan,’ sọ fún Árónì ní ìgbà náà pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Fáráò,’ yóò sì di ejò.”

10. Nígbà náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn, Árónì ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní ìwájú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò.

11. Fáráò sì pe àwọn amòye, àwọn osó àti àwọn onídán ilẹ̀ Éjíbítì jọ, wọ́n sì fi idán wọn ṣe ohun tí Mósè àti Árónì ṣe.

12. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. Ṣùgbọ́n ọ̀pá Árónì gbé ọ̀pá tiwọn mì.

13. Ṣíbẹ̀ ọkàn Fáráò sì yigbì, kò si fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

14. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Ọkàn Fáráò ti di líle, ó kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà ó lọ.

15. Tọ Fáráò lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Náílì láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ.

16. Sọ fún un pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn Hébérù rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni ihà. Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba.

17. Èyí ni Olúwa wí: Nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Náìlì yóò sì di ẹ̀jẹ̀.

18. Àwọn ẹja tí ó wà nínú odò Náìlì yóò kú, odò náà yóò sì máa rùn, àwọn ará Éjíbítì kò sì ni lè mu omi rẹ̀.’ ”

19. Olúwa sọ fún Mósè, “Sọ fún Árónì, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Éjíbítì: Lórí àwọn odò kéékèèke àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi;’ wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Éjíbítì, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé.”

Ka pipe ipin Ékísódù 7