Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 7:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Tọ Fáráò lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Náílì láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ.

16. Sọ fún un pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn Hébérù rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni ihà. Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba.

17. Èyí ni Olúwa wí: Nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Náìlì yóò sì di ẹ̀jẹ̀.

18. Àwọn ẹja tí ó wà nínú odò Náìlì yóò kú, odò náà yóò sì máa rùn, àwọn ará Éjíbítì kò sì ni lè mu omi rẹ̀.’ ”

19. Olúwa sọ fún Mósè, “Sọ fún Árónì, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Éjíbítì: Lórí àwọn odò kéékèèke àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi;’ wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Éjíbítì, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé.”

20. Mósè àti Árónì sí ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Ó gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ni ìwájú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì lu omi odò Náìlì, omi odò náà sì yípadà sí ẹ̀jẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 7