Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 34:7-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1000), ó sì ń dárí jin àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń sọ̀tẹ̀ àti elẹ́sẹ̀. Ṣíbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ìkẹrin.”

8. Mósè foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn.

9. Ó wí pé, “Olúwa, bí èmi bá rí ojú rere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.”

10. Nígbà náà ni Olúwa wí pé: “Èmi dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú yín. Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ èmi yóò se ìyanu, tí a kò tí ì ṣe ní orílẹ̀ èdè ní gbogbo ayé rí. Àwọn ènìyàn tí ìwọ ń gbé láàrin wọn yóò rí i bí iṣẹ́ tí èmi Olúwa yóò ṣe fún ọ ti ní ẹ̀rù tó

11. Ṣe ohun tí èmi pa lásẹ fún ọ lónìí. Èmi lé àwọn ará Ámórì, àwọn ará Kénánì, àwọn ará Kítì àti àwọn ará Jébúsì jáde níwájú rẹ.

12. Má a sọ́ra kí o má ba à bá àwọn ti ó n gbé ilẹ náà tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, nítorí wọn yóò jẹ́ ìdíwọ́ láàrin rẹ.

13. Wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, fọ́ òkúta mímọ́ wọn, kí o sì gé òpó Ásérè wọn. (Ère òrìsà wọn).

14. Ẹ má se sin ọlọ́rùn mìíràn, nítorí Olúwa, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ òjòwú, Ọlọ́run owú ni.

15. “Má a sọ́ra kí ẹ má se bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú; nígbà tí wọ́n bá ń se àgbérè tọ òrìsà wọn, tí wọ́n sì rúbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn.

16. Nígbà tí ìwọ bá yàn nínú àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ ní ìyàwó, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí yóò se àgbérè tọ òrìsà wọn, wọn yóò sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín náà se bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.

17. “Ìwọ kò gbọdọ̀ dá ère kankan

18. “Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa á láṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú osù Ábíbù, nítorí ní osù náà ni ẹ jáde láti Éjíbítì wá.

19. “Gbogbo àkọ́bí inú kọ̀ọ̀kan tèmi ní i se, pẹ̀lú àkọ́bí gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ, bóyá ti màlúù tàbí ti àgùntàn.

Ka pipe ipin Ékísódù 34