Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 30:16-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ìwọ yóò sì gba owó ètùtù náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwọ yóò sì fi lé lẹ̀ fún ìsìn àgọ́ àjọ. Yóò jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níwájú Olúwa, láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.”

17. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mósè pé,

18. “Ìwọ yóò si ṣe agbada idẹ kan, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀.

19. Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀.

20. Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá sún mọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìṣìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún Olúwa,

21. wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Árónì àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandìran wọn.”

22. Olúwa sọ fún Mósè pé,

23. Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta sékélì (kílógíráámù mẹ́fà) tí òjíá sísàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́tàlérúgba (250) sékélì tí kínámónì dídùn, àti kane dídùn àádọ́tàlérúgba (250) sékélì,

24. kaṣia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) sékélì-gbogbo rẹ̀ ní ìlànà sékélì ibi mímọ́ àti hínì òrórò ólífì kan (lítà mẹ́rin).

25. Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò pọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣe-òórùn dídùn tì í ṣe, Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí.

26. Ìwọ yóò sì lò ó láti ya àgọ́ sí mímọ́ àti àpótí ẹ̀rí náà,

27. tábìlì àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà àti ohun èlò rẹ̀, àti pẹpẹ tùràrí,

28. pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀.

29. Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fí ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́.

30. “Ìwọ yóò sì ta òróró sí orí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè sìn mí bí àlùfáà.

Ka pipe ipin Ékísódù 30