Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 3:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kénánì, Hétì, Ámórì, Pérésì, Hífì àti Jébúsì.

9. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, wò ó, igbe àwọn ará Ísírẹ́lì ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Éjíbítì ti se ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà.

10. Ǹjẹ́ nísinsínyìí, lọ, Èmi yóò rán ọ sí Fáráò láti kó àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.”

11. Ṣùgbọ́n Mósè wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Fáráò lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì?”

12. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mósè pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún ọ, tí yóò fihàn pé Èmi ni ó rán ọ lọ; Nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.”

13. Mósè sì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí mo bá tọ̀ àwọn ará Ísírẹ́lì lọ ti mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà?”

14. Ọlọ́run sì sọ fún Mósè pé, “ÈMI NI TI Ń JẸ́ ÈMI NI. Èyí ni ìwọ yóò sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì: ‘ÈMI NI ni ó rán mi sí i yín.’ ”

15. Ọlọ́run sì tún sọ fún Mósè pé, “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù; ti rán mi sí i yín.’ Èyí ni orúkọ mi títí ayérayé, orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí mi láti ìran dé ìran.

Ka pipe ipin Ékísódù 3