Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 29:36-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù. Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún-un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́.

37. Ní ọjọ́ méje ni ìwọ yóò ṣe ètùtù sí pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì sọ ọ́ di mímọ́. Nígbà náà ni pẹpẹ náà yóò jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohúnkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn-án yóò jẹ́ mímọ́.

38. “Èyí ni ìwọ yóò máa fi rúbọ ní orí pẹpẹ náà: Òdọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé.

39. Odọ àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rúbọ ní òwúrọ̀ àti ọ̀dọ́ Àgùntàn èkejì ní àṣálẹ̀.

40. Pẹ̀lú ọ̀dọ́ àgùntàn ti àkọ́kọ́ rúbọ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n fulawa dídára tí a fi ìdámẹ́rin hínì òróró lára ólífì tí a gún, àti ìdámẹ́rin hínì wáìnì bí ẹbọ mímu.

41. Ọ̀dọ́ àgùntàn kejì ni kí ìwọ ki o pa rúbọ ní àṣálẹ̀ ìwọ yóò sì ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu bí ti òwúrọ̀ fún òórun dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe ni sí Olúwa.

42. “Fún ìrandíran tó ń bọ̀, ni ẹ ó máa ṣe ẹbọ sísun nígbà gbogbo ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ níwájú Olúwa. Níbẹ̀ èmi yóò pàdé yín, èmi yóò sì bá a yín sọ̀rò;

43. níbẹ̀ sì tún ni èmi yóò pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a ó sì fi ògo mi ya àgọ́ náà sí mímọ́.

44. “Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ya àgọ́ àjọ náà sí mímọ́ àti pẹpẹ náà, èmi yóò sì ya Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ bí àlùfáà fún mi.

45. Nígbà náà ni èmi yóò máa gbé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èmi yóò sì máa ṣe Ọlọ́run wọn.

46. Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, nítorí kí èmi lè máa gbé àárin wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.

Ka pipe ipin Ékísódù 29