Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 23:12-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára.

13. “Ẹ máa sọ́ra, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo wí fún un yín. Ẹ má se pe orúkọ òrìṣà, kí a má se gbọ́ orúkọ wọn ní ẹnu yín.

14. “Ní ìgbà mẹ́ta ni ìwọ yóò se àjọ̀dún fún mi nínú ọdún.

15. “Ṣe àjọ̀dún àkàrà àìwú; jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje, bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní àkókò tí a ti yàn ní oṣù Ábíbù, nítorí ni oṣù yìí ni ìwọ jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.

16. “Ṣe àjọ̀dún ìkórè pẹ̀lú èso àkọ́so ọ̀gbìn oko rẹ.“Ṣe àjọ̀dún àkójọ oko rẹ ní òpin ọdún, nígbà tí ìwọ bá kó irè oko rẹ jọ tan.

17. “Ní ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ọkùnrin yín yóò máa wá fi ara hàn ní iwájú Olúwa Ọlọ́run.

18. “Ìwọ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ sí mi ti òun ti búrẹ́di tó ní ìwúkàrà.“Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rá ẹbọ àjọ mi ni kò gbọdọ̀ kù títí di òwúrọ̀.

19. “Mú èso àkọ́so ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ.“Ìwọ kò gbọdọ̀ fi omi ọmú ìyá ewúrẹ́ bọ ọmọ ewúrẹ́.

20. “Kíyèsí èmi rán ańgẹ́lì kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún.

21. Fi ara bálẹ̀, kí o sì fetísílẹ̀ sí i, kí o sì gba ohùn rẹ̀ gbọ́; má ṣe sọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kò ní fi àìsedédé yín jin yín, orúkọ mi wà lára rẹ̀.

22. Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì se ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín. Èmi yóò sì fóòrò àwọn tí ń fóòrò yín.

23. Ańgẹ́lì mi yóò lọ níwájú ẹ, yóò sì mú ọ dé ọ̀dọ̀ àwọn ará: Ámórì, Hitì, Párísì, Kénánì, Hífi àti Jébúsì, èmi a sì ge wọn kúrò.

24. Ìwọ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún òrìṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, tàbí kí ẹ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ìwọ kí ó si wó wọn lulẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fọ́ ère òkúta wọ́n túútúú.

25. Ẹ̀yin yóò sí máa sìn Olúwa Ọlọ́run yin, òun yóò si bù sí oúnjẹ rẹ. Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàrin rẹ.

26. Oyún kò ní bàjẹ́ lára obìnrin kan, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan kì yóò yàgàn ni ilẹ̀ rẹ. Èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mi gígùn.

27. “Èmi yóò rán ẹ̀rù mi lọ ṣáájú rẹ, ìdàrúdàpọ̀ yóò sì wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ bá da ojú kọ. Èmi yóò mú kí àwọn ọ̀ta rẹ yí ẹ̀yìn padà sí ọ, kí wọn sì sá ní iwájú rẹ.

28. Èmi yóò rán oyin ṣáájú rẹ láti lé àwọn ará: Hífì, Kénánì àti Hítì kúrò ni ọ̀nà rẹ.

Ka pipe ipin Ékísódù 23