Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 22:8-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ṣùgbọ́n ti a kò bá rí olè náà mú, ẹni tí ó ni ilé náà yóò fi ara hàn níwájú ìdájọ́ láti jẹ́ kí a mọ̀ bí oun fúnrarẹ̀ ni ó gbé ohun ti ó sọnù náà.

9. Bí ẹnìkan bá ni akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, aṣọ tàbí ohun ìní mìíràn tí ó sọnù ní ọ̀nà ti kò bá òfin mu, tí a sì rí ẹni ti ó sọ pé òun ni ó ní ín, àwọn méjèèjì yóò mú ẹjọ́ wọn wá sí iwájú adájọ́. Ẹnikẹ́ni tí adájọ́ bá dá lẹ́bi yóò san án ni ìlọ́po méjì padà fún ẹnìkejì rẹ̀.

10. “Bí ẹnikẹ́ni bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, akọ màlúù, àgùntàn tàbí ẹranko mìíràn láti bá oun tọ́jú rẹ̀, tí ó sì kú, tàbí tí ó fi ara pa, tàbí tí a jí gbé, níbi tí kò ti sí ẹni tí o ṣe àkíyèsí.

11. Wọn yóò búra sí ọ̀rọ̀ náà láàrin ara wọn ni iwájú Olúwa láti fihàn pé òun kò ní ọwọ́ nínú sísọnù ohun ọ̀sìn náà, olóhun gbọdọ̀ gba bẹ́ẹ̀, a kò sì ní san ohunkóhun fún un.

12. Ṣùgbọ́n ti wọ́n bá ji ẹranko náà gbé ni ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, yóò san ẹ̀san padà fún un.

13. Bí ẹranko búburú bá fà á ya, ó ní láti mú àyakù ẹran náà wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, kò sì ní san ẹran náà padà.

14. “Bí ẹnìkan bá sì yá ẹranko lọ́dọ aládúgbò rẹ̀, tí ẹranko náà sì fi ara pa, tàbí kí ó kú nígbà tí ẹni tí ó ni ín kò sí nítòòsí. O gbọdọ̀ san án padà.

15. Ṣùgbọ́n ti ó bá jẹ́ wí pé ó háyà ẹranko náà ni, kò ní láti san ẹ̀san padà, owó tí ó fi háyà ẹranko yìí ni yóò fi tan àdánù ẹranko tí ó kú.

16. “Bí ọkùnrin kan bá fi àrékérekè mú wúndíá kan, ẹni tí kò pinnu láti fẹ́, tí ó sì bá a lòpọ̀, yóò san owó orí rẹ̀, yóò sì fi ṣe aya rẹ̀.

17. Bí baba ọmọbìnrin náà bá kọ̀ jálẹ̀ láti fi fún un ní aya, ó ni láti san owó tó tó owó orí rẹ̀, fún fí fẹ́ ẹ ní wúndíá.

18. “Má ṣe jẹ́ kí àjẹ́ kí ó wà láàyè.

19. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá bá ẹranko lopọ̀ ní a ó pa.

20. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá rúbọ sí òrìṣà yàtọ̀ sí Olúwa nìkan, ni a ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun.

21. “Ẹ má ṣe fi ìyà jẹ àlejò tàbí ni wọ́n lára, nítorí ìwọ pẹ̀lú ti jẹ́ àlejò ni ilẹ̀ Éjíbítì rí.

22. “Má ṣe yan opó tàbí ọmọ òrukàn jẹ.

23. Bí ìwọ bá se bẹ́ẹ̀, bí wọn bá ké pè mi. Èmi yóò sì gbọ́ ohùn igbe wọn.

24. Ìbínú mi yóò ru sókè. Èmi yóò sì fi idà pa ọ. Ìyàwó rẹ yóò di opó, àwọn ọmọ rẹ yóò sì di aláìní baba.

25. “Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrin yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé.

Ka pipe ipin Ékísódù 22