Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 2:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé pápírúsì hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà ati òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú esùnsún ni etí odò Náílì.

4. Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.

5. Nígbà náà ni ọmọbìnrin Fáráò sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Náílì láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárin esùnsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá,

6. ó sí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sunkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hébérù ni èyí.”

7. Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Fáráò pé “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Hébérù wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?”

8. Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá,

9. Ọmọbìnrin Fáráò sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀.

10. Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Fáráò wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mósè, ó wí pé “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”

11. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mósè ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, O ri ará Éjíbítì tí ń lu ará Ébérù, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.

12. Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará Éjíbítì náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn.

13. Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Hébérù méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Hébérù arákùnrin rẹ?”

14. Ọkùnrin náà sì dáhùn pé “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídájọ́ lórí wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ará Éjíbítì?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mósè, ó rò nínú ara rẹ̀ pé “ó ní láti jẹ́ wí pé ohun tí mo ṣe yìí ti di mímọ̀.”

Ka pipe ipin Ékísódù 2