Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 13:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin ṣọ́tọ̀ fún mi. Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ tèmi, ìbáà ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.”

3. Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ́ Éjíbítì, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí Olúwa mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má se jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú.

4. Òní, ní oṣù Ábíbù (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Éjíbítì.

5. Ní ìgbà tí Ọlọ́run mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ ẹ Kénánì, Hítì, Ámórì, Hífì àti ilẹ̀ àwọn Jébúsì; ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí.

6. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa.

7. Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín.

8. Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí Olúwa ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.’

9. Ṣiṣe èyí yóò wà fún àmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ìránlétí ni iwájú orí rẹ tí yóò máa ran ọ létí òfin Olúwa ní ẹnu rẹ. Nítorí Olúwa mú ọ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀.

10. Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún.

11. “Lẹ́yìn tí Olúwa tí mú ọ wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kénánì tí ó sì fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí pẹ̀lú ìbúra fún ọ àti fún àwọn baba ńlá rẹ̀,

12. Ìwọ yóò fi àkọ́bí inú rẹ fún Olúwa. Gbogbo àkọ́bí ti ó jẹ́ akọ ti ẹran ọ̀sìn rẹ ní ó jẹ́ ti Olúwa.

13. Ìwọ yóò fi ọ̀dọ́ àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, ǹjẹ́ kí ìwọ ṣẹ́ ẹ ní ọrùn, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni kí ìwọ kí ó rà padà,

14. “Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní Olúwa fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì, kúrò ní oko ẹrú.

15. Ní ìgbà ti Fáráò ṣe oríkunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, Olúwa pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Éjíbítì, àti ènìyàn àti ẹranko. Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rúbọ sí Olúwa láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin.’

16. Èyí yóò sì jẹ́ àmì ni ọwọ́ yín àti àmì ní iwájú orí yín pé Olúwa mú wa jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá.”

Ka pipe ipin Ékísódù 13