Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 12:28-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Àwọn Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè àti Árónì.

29. Ní ọ̀gànjọ́ òru Olúwa kọlu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Éjíbítì, láti orí àkọ́bí. Fáráò tí ó wà ní orí ìtẹ́ títí dé orí àkọ́bí ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n àti àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú.

30. Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn ara Éjíbítì dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, igbe ẹkún ńlá sì gba gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, nítorí kò sí ilé kan tí ó yọ sílẹ̀ tí ènìyàn kan kò ti kú.

31. Fáráò sì ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì ní òru, ó sì wí pé, “Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì! Ẹ lọ láti sin Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹ ti béèrè.

32. Ẹ kó agbo àgùntàn yín àti agbo màlúù yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti sọ, kí ẹ sì máa lọ, kí ẹ sì súre fún mi.”

33. Àwọn ara Éjíbítì ń rọ àwọn ènìyàn náà láti yára máa lọ kúrò ní ilẹ̀ wọn. Wọ́n wí pé, “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ gbogbo wa ni yóò kú!”

34. Àwọn ènìyàn náà sì mú ìyẹ̀fun pípò kí wọn tó fi ìwúkàrà sí i, wọ́n gbe le èjìká wọn nínú ọpọ́n tí wọ́n ti fi aṣọ dì.

35. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè ti sọ fún wọn. Wọ́n sì béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà àti fún aṣọ pẹ̀lú.

36. Olúwa ti mú kí àwọn ènìyàn yìí rí ojú rere àwọn ará Éjíbítì wọ́n sì fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún, wọ́n sì ko ẹrù àwọn ará Éjíbítì.

37. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rìn láti Rámẹ́sẹ́sì lọ sí Sukoti. Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọ̀gbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ni iye láì ka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.

Ka pipe ipin Ékísódù 12