Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 11:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísínsìn yìí, Olúwa sọ fún Mósè pé èmi yóò mú ìyọnu kan sí i wá sí orí Fáráò àti ilẹ̀ Éjíbítì. Lẹ́yìn náà yóò jẹ́ kí ẹ̀yín kí ó lọ kúrò níhín yìí, nígbà tí ó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ yóò lé yín jáde pátápátá.

2. Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé kí tọkùnrin tobìnrin wọn béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀.

3. (Olúwa jẹ́ kí wọn rí ojú rere àwọn ará Éjíbítì, pàápàá, Mósè fún ra rẹ̀ di ènìyàn pàtàkì ní ilẹ̀ Éjíbítì ní iwájú àwọn ìjòyè Fáráò àti ní iwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú).

4. Nígbà náà ni Mósè wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ‘Ní ọ̀gànjọ́ òru èmi yóò la ilẹ̀ Éjíbítì kọjá.

5. Gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin tí ó wà ní ilẹ̀ Éjíbítì ni yóò kú, bẹ̀rẹ̀ lórí àkọ́bí ọkùnrin Fáráò tí ó jòkòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, tí ó fi dé orí àkọ́bí ọmọkùnrin ti ẹrú-bìnrin tí ń lọ ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú.

6. Igbe ẹkún ńlá yóò sọ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì. Irú ohun búburú tí kò sẹlẹ̀ rí tí kò sí tún ni sẹlẹ̀ mọ́.

Ka pipe ipin Ékísódù 11