Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 10:14-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n wà ní ibi gbogbo ní orí ilẹ̀ ní àìmoye, ṣáájú àkókò yìí kò sí irú ìyọnu Esú bẹ́ẹ̀, rí kò sì ní sí irú rẹ mọ́ lẹ́yìn èyí.

15. Wọ̀n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú. Wọ́n ba gbogbo ohun tó kù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́; gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi. Kò sí ewe tí ó kù lórí igi tàbí lorí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Íjibítì.

16. Fáráò yára ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín àti sí i yín pẹ̀lú.

17. Nísinsìnyìí ẹ dárí jín mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”

18. Nígbà náà ni Mósè kúrò ní iwájú Fáráò ó sì gbàdúrà sí Olúwa.

19. Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀ oòrùn wá láti gbá àwọn Esú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Éjíbítì lọ sínú òkun pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ Esú kan kò ṣẹ́ kù sí orí ilẹ̀ Éjíbítì.

20. Ṣíbẹ̀ Olúwa ṣe ọkàn Fáráò le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

21. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run kí okùnkùn báà le bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì; àní òkùnkùn biribiri.”

22. Nígbà náà ni Mósè gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì fún ọjọ́ mẹ́ta. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìmọ́lẹ̀ ní ibi tí wọn ń gbé.

23. Kò sí ẹni tí ó le è ríran rí ẹlòmíràn tàbí kí ó kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ̀ mẹ́ta. Ṣíbẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ̀lì ni ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé.

24. Fáráò sì ránṣẹ́ pe Mósè ó sì wí fún un pé, “Lọ sìn Olúwa, kódà àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé lè lọ pẹ̀lú yín, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó fi agbo àgùntàn àti agbo màlúù yín sílẹ̀.”

25. Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, “Ìwọ gbọdọ̀ fún wa láàyè láti rúbọ àti ọrẹ ẹbọ sísun ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa.

26. Àwọn ohun ọ̀sìn wa gbọdọ̀ lọ pẹ̀lú wa, a kì yóò fi pátákò ẹṣẹ̀ ẹran sílẹ̀. A ní láti lò lára wọn fún sínsìn Olúwa Ọlọ́run wa, ìgbà tí a bá sì dé ibẹ̀ ni a ó to mọ̀ ohun ti a ó lò láti fi sìn Olúwa.”

27. Ṣùgbọ́n Olúwa ṣé ọkàn Fáráò le, kò sì ṣetan láti jẹ́ kí wọn lọ.

28. Fáráò sọ fún Mósè pé, “Kúrò ní iwájú mi! Rí i dájú pé o kò wá sí iwájú mi mọ́! Ọjọ́ tí ìwọ bá rí ojú mi ni ìwọ yóò kú.”

29. Mósè sì dáhùn pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wí, “Èmi kí yóò wá sí iwájú rẹ mọ́.”

Ka pipe ipin Ékísódù 10