Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 1:9-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ “Ẹ wò ó, àwọn ará Ísírẹ́lì ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa.

10. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.”

11. Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pítómi àti Ráméṣéṣì gẹ́gẹ́ bí ìlú ìkó ìṣúra pamọ́ sí fún Fáráò.

12. Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, ti wọn sì ń tàn kálẹ̀; Nítorí náà, àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rù nítorí àwọn ará Ísírẹ́lì.

13. Wọ́n sì mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekú láìkáánú wọn.

14. Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ ẹ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Éjíbítì ń lò wọ́n ní ìlòkulò.

15. Ọba Éjíbítì sọ fún àwọn agbẹ̀bí Hébérù ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣífúrà àti Púà pé:

16. “Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Hébérù, tí ẹ sì kíyèsí wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láàyè.”

17. Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Éjíbítì ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láàyè.

18. Ọba Éjíbítì pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí?, Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si?”

19. Àwọn agbẹ̀bí náà sì dá Fáráò lóhùn pé, “Àwọn obìnrin Hébérù kò rí bí àwọn obìnrin Éjíbítì, wọ́n ní agbára, wọ́n sì ti máa ń bí ọmọ kí àwọn agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”

20. Nítorí náà Ọlọ́run ṣàánú fún àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń le sí i, wọ́n sì ń pọ̀ sí i jọjọ.

21. Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, Ọlọ́run sì fún wọn ni ìdílé ti wọn.

22. Nígbà náà ni Fáráò pàṣẹ yìí fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ pé; “Gbogbo ọmọkùnrin tí a bí ni kí ẹ gbé jù sínú odò Náílì, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọbìnrin ni kí ẹ jẹ́ kí wọn ó wà láàyè.”

Ka pipe ipin Ékísódù 1