Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 28:28-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà.

29. Ní ọ̀sán gangan ìwọ yóò fi ọwọ́ talẹ̀ kiri bí ọkùnrin afọ́jú nínú òkùnkùn ìwọ kì yóò ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí o bá ń ṣe, ojoojúmọ́ ni wọn yóò máa ni ọ́ lára àti jà ọ́ ní olè, tí kò sì ní í sí ẹnìkan láti gbà ọ́.

30. Ìwọ yóò gba ògo láti fẹ obìnrin kan ṣùgbọ́n ẹlòmíràn yóò gbà á yóò sì tẹ́ ẹ́ ní ògo. Ìwọ yóò kọ́ ilé, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò gbé ibẹ̀. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kò tilẹ̀ ní gbádùn èṣo rẹ.

31. Màlúù rẹ yóò di pípa níwájú ù rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò jẹ ìkankan nínú rẹ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ yóò sì di mímú pẹ̀lú agbára kúrò lọ́dọ̀ rẹ, a kì yóò sì da padà. Àgùntàn rẹ yóò di mímú fún àwọn ọ̀ta rẹ, ẹnìkankan kò sì ní gbà á.

32. Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ yóò di mímú fún àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, ìwọ yóò sì fi ojú ù rẹ sọ́nà dúró dè wọ́n láti ọjọ́ dé ọjọ́, ìwọ yóò sì jẹ́ aláìlágbára láti gbé ọwọ́.

33. Èṣo ilẹ̀ rẹ àti gbogbo iṣẹ́ làálàá rẹ ni orílẹ̀-èdè mìíràn tí ìwọ kò mọ̀ yóò sì jẹ, ìwọ yóò jẹ́ kìkì ẹni ìnilára àti ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀

34. Ìran tí ojú ù rẹ yóò rí, yóò sọ ọ́ di òmùgọ̀.

35. Olúwa yóò lu eékún àti ẹṣẹ̀ rẹ pẹ̀lú oówo dídùn tí kò le san tán láti àtẹ́lẹṣẹ̀ méjèèjì rẹ lọ sí òkè orí rẹ.

36. Olúwa yóò lé ọ àti ọba tí ó yàn lóríì rẹ lọ sí orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀ tàbi ti àwọn baba rẹ kò mọ̀. Ibẹ̀ ni ìwọ̀ yóò sì sin ọlọ́run mìíràn, ọlọ́run igi àti òkúta.

Ka pipe ipin Deutarónómì 28