Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 1:4-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Èyí sẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun Síhónì ọba àwọn Ámórì, tí ó jọba ní Hésíbónì, àti Ógù ọba Básánì ni ó ṣẹ́gun ní Édírénì, ẹni tí ó jọba ní Ásítarótù.

5. Ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì tí ó wà nínú ilẹ̀ Móábù ni Mósè ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàlàyé àwọn òfin wọ̀nyí wí pé:

6. Olúwa Ọlọ́run wa bá wa sọ̀rọ̀ ní Hórébù pé, “Ẹ ti dúró ní orí òkè yìí pẹ́ tó.

7. Ẹ yípadà kí ẹ sì tẹ̀ṣíwájú ní ìrìnàjò yín lọ sí ilẹ̀ òkè àwọn ará Ámórì: Ẹ tọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń gbé agbégbé lọ ní aginjù, ní àwọn orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní Nágéfì àti ní etí òkun, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kénánì àti lọ sí Lẹ́bánónì, títí fi dé odò ńlá Éfúrétì.

8. Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín: Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí Olúwa ti wí pé òun yóò fún àwọn baba yín: fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.”

9. Mo wí fún-un yín nígbà náà pé, “Èmi nìkan kò lè dá ẹrù u yín gbé mọ́.

10. Olúwa Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀ lónìí, ẹ̀yin sì ti pọ̀ bí ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run.

11. Kí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín sọ yín di púpọ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún sí i, kí ó sì bùkún un yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.

12. Báwo ni èmi nìkan ṣe lè má a ru àjàgà àti ìsòro yín àti èdè àìyedè yín?

13. Ẹ yan àwọn ọlọgbọ́n, olóye àti àwọn ẹni àpọ́nlé, láti inú ẹ̀yà yín kọ̀ọ̀kan, èmi yóò sì fi wọ́n ṣe olórí yín.”

14. Ẹ̀yin sì dá mi lóhùn wí pé, “Ohun tí ìwọ ti gbérò láti ṣe n nì dára.”

15. Bẹ́ẹ̀ ni mo yan àwọn aṣáájú ẹ̀yà yín, àwọn ọlọgbọ́n àti ẹni àpọ́nlé láti ṣe àkóso lórí yín: gẹ́gẹ́ bí olùdarí ẹgbẹgbẹ̀rún, ọgọgọ́rùn-ún, àràádọ́ta, ẹ̀wẹ̀ẹ̀wá àti gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn ẹ̀yà.

Ka pipe ipin Deutarónómì 1