Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 8:19-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ó sọ wí pé: “Èmi yóò sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ní ìgbà ìbínú, nítorí ìran náà jẹ mọ́ àkókò ohun tí a yàn nígbà ìkẹyìn.

20. Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Médíánì àti Páṣíà.

21. Òbúkọ onírun náà ni ọba Gíríkì, ìwo ńlá ti ó wà láàrin ojú u rẹ̀ ni ọba àkọ́kọ́.

22. Ìwo mẹ́rin ti ó dípo ọ̀kan tí ó kán dúró, èyí dúró gẹ́gẹ́ bí ìjọba mẹ́rin tí ó dìde láti orílẹ̀ èdè e rẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò ní ní irú agbára kan náà.

23. “Ní ìgbà ìkẹyìn ìjọba wọn, nígbà tí ìwà búburú àwọn ọlọ̀tẹ̀ bá burú gidigidi ọba tí ojú u rẹ̀ le koko, balógun rìkísí yóò dìde.

24. Yóò di alágbára, ṣùgbọn tí kì í ṣe nípa agbára rẹ̀. Yóò sì máa ṣe ìparun tí yóò ya ni lẹ́nu, yóò sì máa ṣe àṣeyọri nínú ohun gbogbo tó ń ṣe. Yóò sì run àwọn alágbára àti àwọn ènìyàn mímọ́.

25. Nípa àrékérekè rẹ̀, yóò mú kí ẹ̀tàn gbèrú, yóò gbé ara rẹ̀ ga nínú ọkàn rẹ̀, nígbà tí wọ́n rò wí pé àlàáfíà dé, yóò sì pa àwọn ènìyàn run, nígbà tí wọn kò rò tẹ́lẹ̀, yóò sì lòdì sí olórí àwọn ọmọ aládé, ṣíbẹ̀, a ó paárun ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa agbára ènìyàn.

26. “Ìran alẹ́ àti ti òwúrọ̀, tí a fi hàn ọ́ jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n pa ìran náà mọ́, nítorí pé, ó jẹ mọ́ ti ọjọ́ iwájú”

27. Èmi Dáníẹ́lì sì ṣe àárẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan. Nígbà náà, mo dìde, mo sì ń bá isẹ́ ọba lọ. Ìran náà sì bàmí lẹ́rù, kò sì yé mi.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 8