Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 8:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Beliṣáṣárì ọba, èmi Dáníẹ́lì rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀.

2. Nínú ìran náà, mo rí ara mi nínú ilé ìṣọ́ ní Súsáni ní agbègbè ìjọba Élámù: nínú ìran náà mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Úláì.

3. Mo wo òkè mo sì rí àgbò kan tí ó ní ìwo méjì níwájú ù mi, ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Úláì, àwọn ìwo méjèèje sì gùn. Ṣùgbọ́n ọ̀kan gùn ju èkejì lọ, èyí tí ó gùn jù ni ó yọ jáde kẹ́yìn.

4. Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, sí àríwá, àti sí gúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó leè dojú kọọ́, kò sí ẹnìkan tí ó leè yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára.

5. Bí mo ṣe ń ronú nípa èyí, lójijì ni òbúkọ kan tí ó ní ìwo láàrin ojú u rẹ̀ méjèèjì jáde láti ìhà ìwọ̀ oòrùn, ó la gbogbo ayé kọjá láì fi ara kan ilẹ̀.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 8