Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 10:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nígbà náà ni ó tẹ̀ṣíwájú, pé, “Má ṣe bẹ̀rù Dáníẹ́lì. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fi ọkàn rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì wá nítorí ọ̀rọ̀ náà.

13. Ṣùgbọ́n ọmọ aládé ìjọba Páṣíà dá mi dúró fún ọjọ́mọ́kànlélógún. Nígbà náà ni Máíkẹ́lì, ọ̀kan lára ìjòyè àwọn ọmọ aládé, wá láti ràn mi lọ́wọ́, nítorí a dá mi dúró níbẹ̀ pẹ̀lú ọba Páṣíà.

14. Ní ìsinsinyí mo wá láti ṣàlàyé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú, nítorí ìran náà ń sọ nípa ọjọ́ iwájú.”

15. Bí ó sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún mi, mo sì dorí kodò mo sì dákẹ́.

16. Nígbà náà, ni ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kan ètè mi, mo la ẹnu mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀, mo sọ fún ẹni tí ó dúró níwájú mi, “Ìrònú sì mú mi, nítorí ìran náà, Olúwa mi, n kò sì ní okun.

17. Ǹjẹ́ báwo ni èmi ìránṣẹ́ ẹ̀ rẹ ṣe lè bá ọ sọ̀rọ̀, Olúwa mi? Agbára mi ti lọ, agbára káká ni mo fi ń mí.”

18. Ẹ̀wẹ̀, ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi ní agbára.

19. Ó sì wí pé, “Má se bẹ̀rù, ìwọ ọkùnrin tí a yàn fẹ́ gidigidi.” Bí ó ti sọ̀rọ̀ fún mi, ara à mí sì le, mo sọ pé, “Má a wí Olúwa mi, níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní agbára.”

20. Nígbà náà, ni ó wí pé, “Sé o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá? Láìpẹ́ èmi yóò yípadà lọ bá àwọn ọmọ aládé Páṣíà jà, nígbà tí mo bá lọ àwọn ọmọ aládé Gíríkì yóò wá;

21. ṣùgbọ́n ní àkọ́kọ́, èmi yóò sọ ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé òtítọ́ fún ọ. (Kò sí ẹni tí ó kún mi lọ́wọ́ fún nǹkan wọ̀nyí bí kò ṣe Máíkẹ́lì, ọmọ aládé e yín.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 10