Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 7:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ ọ́, dáríjìn! Báwo ni Jákọ́bù yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”

3. Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí;“Èyí kò ni sẹlẹ̀,” ni Olúwa wí.

4. Èyí ni ohun ti Olúwa Ọlọ́run fi hàn mí: Olúwa Ọlọ́run ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run.

5. Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Ọlọ́run jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jákọ́bù yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”

6. Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí.“Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa alágbára wí

7. Èyí ni ohun tí ó fi hàn mí: Olúwa dúró ní ẹ̀gbẹ́ odi ti a fi okùn ìwọ̀n mọ́, ti òun ti okùn-ìwọ̀n tí ó rún ni ọwọ́ rẹ̀.

8. Olúwa sì bi mi pé, “Ámósì, kí ni ìwọ rí?”Mo dáhùn pé, “Okùn-ìwọ̀n.”Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Wòó, Èmí ń gbé okùn-ìwọ̀n kalẹ láàárin àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi; Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́

9. “Ibi gíga Ísáákì wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoroàti ibi mímọ Ísírẹ́lì wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro.Èmi yóò sì fi idà dide sí ilé Jéróbóámù.”

10. Nígbà náà Ámásáyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì ránṣẹ́ sí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, wí pé: “Ámosì ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárin gbùngbùn Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.

11. Nítorí èyí ni ohun ti Ámosì ń sọ:“ ‘Jéróbóámù yóò ti ipa idà kú,Lóótọ́ Ísírẹ́lì yóò lọ sí ìgbèkùn,jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”

Ka pipe ipin Ámósì 7