Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 5:17-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàràNítorí èmi yóò la àárin yín kọjá,”ni Olúwa wí.

18. Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́nítorí ọjọ́ Olúwakí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa?Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́

19. Yóò dàbí ọkùnrin tí ó sá láti ẹnu àmọ̀tẹ́kùn.Tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu ẹkùnyóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọtí ó simi lé ògiri ilé rẹ̀tí ejò sì bù ú ṣán.

20. Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀?Tí ó sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀

21. “Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àṣè ẹ̀sìn in yínÈmi kò sì ní inú dídùn sí àpèjọ yín

22. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ọrẹ sísun àti ọrẹ ọkà wáÈmi kò ní tẹ́wọ́n gbà wọ́nBí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.Èmi kò ní náání wọn.

23. Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìnÈmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.

24. Jẹ́ kí òtítọ́ ṣàn bí odòàti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ

25. “Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wání ogójì ọdún ní ihà ìwọ ilé Ísírẹ́lì?

26. Ẹ̀yin ń gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yínibùgbé àwọn òrìṣà yínàní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ,èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.

27. Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Dámásíkù,”ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.

Ka pipe ipin Ámósì 5