Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 9:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nípaṣẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogunilẹ̀ náà yóò di gbígbẹàwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná,ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.

20. Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n,ní apá òsì, wọn yóò jẹṣùgbọ́n, kò ní tẹ́wọn lọ́rùn.Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara ọmọ rẹ̀.

21. Mánásè yóò máa jẹ Éfáímù, nígbà tí Éfáímù yóò jẹ Mánásèwọn yóò parapọ̀ dojúkọ Júdà.Ṣíbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúròỌwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.

Ka pipe ipin Àìsáyà 9