Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 61:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Láti kéde ọdún ojúrere Olúwaàti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

3. àti láti pèṣè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Ṣíhónìláti dé wọn ládé ẹ̀yẹ dípò eérú,òróró ìdùnnú dípò ìbànújẹ́,àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúùru ọkàn.A ó sì pè wọ́n ní óákù òdodo,irúgbìn Olúwaláti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

4. Wọn yóò tún àwọn ahoro ìṣẹ̀ǹbáyé kọ́wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́tijọ́ náà bọ̀ sípò;wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padàtí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.

5. Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.

6. A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdèàti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.

Ka pipe ipin Àìsáyà 61