Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 6:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn mi lọ kí o sì wí pé;“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;ní rírí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’

10. Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,mú kí wọn kútíkí o sì pa ojú wọn dé.Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò fi ojú u wọn ríran,ki wọn má ba à fi etíi wọn gbọ́ràn,kí òye máa ba à yé wọn ní ọkàn an wọnkí wọn má ba à yípadà kí a má ba à sì wò wọ́n sàn.”

11. Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó Olúwa?”Òun sì dáhùn pé:“Títí tí gbogbo ìlú ńlá yóò fi dahoroláìsí olùgbé nínú un rẹ̀ mọ́,títí tí gbogbo ilé yóò fi di ìkọ̀sílẹ̀tí gbogbo ilé yóò sì di àlàpà àti ahoro,

12. títí tí Olúwa yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà rérétí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátapáta.

13. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀náà, yóò sì tún pàpà padà parunṢùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹ́rẹ́bíńtì àti óákùti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté níilẹ̀ náà.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 6