Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 56:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà,nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsíàti òdodo mi ni a ó fi hàn láìpẹ́ jọjọ.

2. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí,ọkùnrin náà tí ó dì í mú ṣinṣin,tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bàá jẹ́,tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”

3. Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀mọ́ Olúwa sọ wí pé,“Olúwa yóò yà mí ṣọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”Àti kí ìwẹ̀fà kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé“Igi gbígbẹ lásán ni mí.”

4. Nítorí pé ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mití wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin

5. fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹ́ḿpìlì àti àgbàlá rẹ̀ìrántí kan àti orúkọ kantí ó sànju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrinÈmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayétí a kì yóò ké kúrò.

6. Àti àwọn àjèjì tí ó ṣo ara wọn mọ́ Olúwaláti sìn ín,láti fẹ́ orúkọ Olúwaàti láti foríbalẹ̀ fún ungbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—

7. àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mièmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.Ọrẹ síṣun àti ẹbọ wọnni a ó tẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi;nítorí a ó máa pe ilé mi níilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀ èdè.”

8. Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé—ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Ísírẹ́lì jọ:“Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lúu wọnyàtọ̀ sí àwọn tí a ti kó jọ.”

9. Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú un pápá,ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!

Ka pipe ipin Àìsáyà 56