Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 52:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jí, jí, Ìwọ Ṣíhónì,wọ ara rẹ ní agbára.Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,Ìwọ Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́ n nì.Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́kì yóò wọ inú un rẹ mọ́.

2. Gbọn eruku rẹ kúrò;dìde ṣókè, kí o sì gúnwà, Ìwọ Jérúsálẹ́mù.Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,Ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbékùn Ṣíhónì.

3. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí;“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”

4. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi ṣọ̀kalẹ̀lọ sí Éjíbítì láti gbé;láìpẹ́ ni Áṣíríà pọ́n wọn lójú.

5. “Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí.“Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,àwọn tí ó sì ń jọba lé wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”ni Olúwa wí.“Àti ní ọjọọjọ́orúkọ mi ni a ṣọ̀rọ̀ òdì sí nígbà gbogbo.

6. Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀pé Èmi ni ó ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”

7. Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkèẹṣẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìn rere ayọ̀ wá,tí wọ́n kéde àlàáfíà,tí ó mú ìyìn rere wá,tí ó kéde ìgbàlà,tí ó sọ fún Ṣíhónì pé,“Ọlọ́run rẹ ń jọba!”

8. Tẹ́tísílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn ṣókèwọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀.Nígbà tí Olúwa padà sí Ṣíhónì,wọn yóò rí i pẹ̀lú ojúu wọn.

9. Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀,ẹ̀yin ahoro Jérúsálẹ́mù,nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú,ó sì ti ra Jérúsálẹ́mù padà.

10. Olúwa yóò sí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ní ojú gbogbo orílẹ̀ èdè,àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò ríìgbàlà Ọlọ́run wa.

Ka pipe ipin Àìsáyà 52