Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 47:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀ṣíwájú títí láé—ọba-bìnrin ayérayé!’Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí nǹkan wọ̀nyítàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.

8. “Nísinsìn yìí, tẹ́tísílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dátí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹtí o sì ń sọ fún ara rẹ pé,‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi.Èmi kì yóò di opótàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’

9. Méjèèjì yìí ni yóò wá sóríì rẹláìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà:pípàdánù ọmọ àti dídi opó.Wọn yóò wá sóríì rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹàti àwọn èpè rẹ tí kì í ṣélẹ̀.

10. Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹó sì ti wí pé, ‘kò sí ẹni tí ó rí mi?’Ọgbọ́n àti òye rẹ ti sì ọ́ lọ́nànígbà tí o wí fún ara rẹ pé,‘Èmi ni, kò sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi.’

11. Ìparun yóò dé bá ọbẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò.Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò;òfò kan tí o kò le ròtì niyóò wá lójijì sí oríì rẹ.

12. “Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹàti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo,tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá.Bóyá o le è ṣàṣeyọrí,bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.

13. Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà nió ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀!Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú,Àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀láti oṣù dé oṣù,jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.

14. Lóòótọ́ wọ́n dàbí pòpó;iná ni yóò jó wọn dànù.Wọn kò kúkú lè gba ara wọn làlọ́wọ́ agbára iná náà.Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbónáníhìnín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.

15. Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìígbogbo èyí ní o tí síṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe.Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀;kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 47