Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 44:2-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ohun tí Olúwa wí nìyìíẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́láti inú ìyá rẹ wá,àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú:Má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù, ìránṣẹ́ mi,Jéṣúrúnì ẹni tí mo ti yàn.

3. Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹàti àwọn odò ni ilẹ̀ gbígbẹ;Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,àti ìbùkún mi sóri àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.

4. Wọn yóò dàgbà ṣókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínúpápá oko tútù,àti gẹ́gẹ́ bí igi póǹpóla léti odò tí ń sàn.

5. Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’;òmìíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jákọ́bù;bẹ́ẹ̀ ni òmìíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, Ti Olúwa,yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Ísírẹ́lì.

6. “Ohun tí Olúwa wí nìyìíọba Ísírẹ́lì àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun:Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,lẹ́yin mi kò sí Ọlọ́run kan.

7. Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú miKí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdíàwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ aṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.

8. Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọàṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ típẹ́típẹ́?Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kanha ń bẹ lẹ́yìn mi?Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”

9. Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́kò jámọ́ nǹkankan.Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;wọ́n jẹ́ aláìmọ́kan sí ìtìjú ara wọn.

10. Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?

11. Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójú tì;àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sìfi ìdúró wọn hàn;gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú Ìpayà àti àbùkù.

12. Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò,ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú;ó fi òòlù ya ère kan,ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀,Ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un;kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.

13. Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ̀n ọ́nó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe àmì sí ara rẹ̀,Ó tún fi ṣísẹ́lì họ ọ́ jádeó tún fi kọ́ḿpáásì ṣe àmì sí i.Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàngẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀,kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà.

Ka pipe ipin Àìsáyà 44