Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 44:18-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Wọn kò mọ nǹkankan, nǹkankan kò yé wọn;a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkankan;bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkankan.

19. Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òyeláti sọ wí pé,“Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;Mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,Mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kannínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”

20. Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ̀tàn ni ó sì í lọ́nà;òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé“Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”

21. “Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, Ìwọ Jákọ́bùnítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, Ìwọ Ísírẹ́lì.Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe,Èmi Ísírẹ́lì, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.

22. Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kùrukùru,àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀.Padà sọ́dọ̀ mi,nítorí mo ti rà ọ́ padà.”

23. Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí;kígbe ṣókè, Ìwọ ilẹ̀ ayé níṣàlẹ̀.Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá,ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín,nítorí Olúwa ti ra Jákọ́bù padà,ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Ísírẹ́lì.

24. “Ohun tí Olúwa wí nìyìíOlùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́láti inú ìyá rẹ wá:“Èmi ni Olúwatí ó ti ṣe ohun gbogbotí òun nìkan ti na àwọn ọ̀runtí o sì tẹ́ ayé pẹrẹṣẹ òun tìkálára rẹ̀,

25. “ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́tí ó sì sọ àwọn tí ń woṣẹ́ fún ni di òmùgọ̀,tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọgbọ́n délẹ̀tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,

26. ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jádetí ó sì mú àṣọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ,“ẹni tí ó wí nípa ti Jérúsálẹ́mù pé,‘a ó máa gbénú un rẹ̀,’àti ní ti àwọn ìlú Júdà, ‘A ó tún un kọ́,’àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀sípò,’

27. ta ni ó sọ fún omi jínjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ,èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’

28. ta ni ó sọ nípa Ṣáírọ́ọ́ṣì pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn miàti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́;òun yóò sọ nípa Jérúsálẹ́mù pé, “Jẹ́ kí a tún un kọ́,”àti nípa tẹ́ḿpìlì, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’

Ka pipe ipin Àìsáyà 44