Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 42:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró,àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀;Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀ èdè.

2. Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe ṣókè,tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ ṣókè ní òpópónà.

3. Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́àti òwú-àtùpà tí ń jó tan an lọlòun kì yóò fẹ́ pa.Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá;

4. Òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sìtítí tí yóò fi fi ìdájọ́ mulẹ̀ ní ayé.Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètíi wọn sí.”

5. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wíẸni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n ṣóde,tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú un wọn,Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémíàti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú un rẹ̀:

6. “Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo;Èmi yóò di ọwọ́ọ̀ rẹ mú.Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyànàti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà

7. láti la àwọn ojú tí ó fọ́,láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbúàti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀nàwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.

8. “Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí!Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmìíràntàbí ìyìn mi fún ère-òrìṣà.

9. Kíyèsí i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé,àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé;kí wọn tó hù jádemo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”

10. Kọ orin titun sí Olúwaìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá,ẹ̀yin tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkun, àtiohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú un wọn.

11. Jẹ́ kí ihà àti àwọn ìlúu rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn ṣókè;jẹ́ kí ibùdó ti àwọn igi kédárì ń gbé máa yọ̀.Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Ṣẹ́là kọrin fún ayọ̀;jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.

12. Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwaàti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.

13. Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára,gẹ́gẹ́ bí jagunjagun yóò ti gbé ohun ipá rẹ̀ ṣókè;pẹ̀lú ariwo, òun yóò ké igbe ogunòun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀ta rẹ̀.

14. “Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́,mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró.Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí,mo ṣunkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ.

15. Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahorotí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù;Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣùn ó sì gbẹ àwọn adágún.

16. Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀,ní ipa-ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ;Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájúu wọnàti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná.Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí;Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

17. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà,tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.

Ka pipe ipin Àìsáyà 42