Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 36:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba Heṣekáyà, Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Júdà ó sì kó gbogbo wọn.

2. Lẹ́yìn náà, ọba Áṣíríà rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì sí ọba Hẹṣikáyà ní Jérúsálẹ́mù. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúsàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá Alágbàfọ̀,

3. Eliákímù ọmọ Hílíkáyà alábojútó ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti Jóà ọmọ Áṣáfù akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀.

4. Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Heṣekáyà,“ ‘Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Áṣíríà sọ pé: Lóríi kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé?

5. Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ aṣán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi?

6. Wò ó nísinsìn yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì ẹ̀rúnrún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sìí dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Fáráò ọba Éjíbítì sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e.

7. Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Heṣekáyà ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Júdà àti Jérúsálẹ́mù pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájúu pẹpẹ yìí”?

8. “ ‘Ẹ wá nísinsìn yìí, bá ọ̀gá mi pàmọ̀ pọ̀, ọba Ásíríà: Èmi yóò fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí!

9. Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kanṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn ìjòyè ọ̀gá mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin?

10. Síwájú sí i, ǹjẹ́ mo wa lè wá bá ilẹ̀ yìí jà kí n sì pa á run láìsí Olúwa? Olúwa fún rara rẹ̀ ló sọ pé kí n bá orílẹ̀ èdè yìí jà kí n sì paárun.’ ”

11. Lẹ́yìn náà ni Eliákímù, Ṣébínà àti Jóà sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì, nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 36