Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 34:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Idà Olúwa kún fún ẹ̀jẹ̀a mú un ṣanra fún ọ̀rá,àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-agùtàn àti ewurẹ,fún ọ̀rá iwe àgbò—nítorí Olúwa ni ìrúbọ kan ní Bósírà,àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Édómù.

7. Àti àwọn àgbáǹréré yóòba wọn ṣọ̀kalẹ̀ wá,àti àwọn ẹgbọ̀rọ̀ màlúùpẹ̀lú àwọn akọ màlúù,ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin,a ó si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di Ọlọ́ràá.

8. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san Olúwa ni,àti ọdún ìsanpadà,nítorí ọ̀ràn Ṣíhónì.

9. Odò rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà,àti eruku rẹ̀ di imí-ọjọ́,ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì di ọ̀dà tí ń jóná.

10. A ki yóò paá ní òru tàbí ní ọ̀sán,èéfín rẹ̀ yóò gòkè láéláé:yóò dahoro láti ìran dé ìran,kò sí ẹnìkan tí yóò là á kọjá láéàti láéláé.

11. Ṣùgbọ́n ẹyẹ àṣá,àti àkàlà ni yóò ni ín,àti òun yóò sì na okùn-ìwọ̀n ìparunsóríi rẹ̀,àti òkúta ohun rudurùdu sórí àwọn ọlọ́lá rẹ̀.

12. Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀ti wọn ó pè wá sí ìjọba,gbogbo àwọn olóríi rẹ̀ yóò sì di asán.

13. Ẹ̀gún yóò sì hù jádenínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí,ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀.Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátáàti àgbàlá fún àwọn òwìwí.

14. Àwọn ẹran ijùàti àwọn ọ̀wàwà ni yóò pàdé,àti sátírè kan yóò máa kọ sí èkejìí rẹ̀,iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú,yóò sì rí ibi isinmi fún ara rẹ̀.

15. Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ ṣíbẹ̀,yóò yé, yóò sì pa,yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀:àwọn gúnnugún yóò péjọ ṣibẹ̀ pẹ̀lú,olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀.

16. Ẹ wá a nínú ìwé Olúwa, ẹ sì kà á:Ọ̀kan nínú wọ̀nyí kì yóò yẹ̀,kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ ìkejìi rẹ̀ kù:nítorí Olúwa ti pàṣẹẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọẸ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ.

17. Ó ti di ìbò fún wọn,ọwọ́ rẹ̀ sì ti pín in fún wọnnípa títa okùn,wọn ó jogún rẹ̀ láéláé,láti ìran dé ìranni wọn ó máa gbé inú un rẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 34