Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 33:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣátì,kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nàA ti ba àdéhùn jẹ́,a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí,a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.

9. Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù,ojú ti Lẹ́bánónì ó sì ṣáṢárónì sì dàbí aginjù,àti Báṣánì òun Kámẹ́lì rẹ àwọn èwe wọn.

10. “Ní ìsinsìn yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí.“Ní ìsinsìn yìí ni a ó gbé mi ga,ní ìsinsìn yìí ni a ó gbé mi sókè.

11. Ìwọ lóyún fùfùléèléè,o sì bí koríko;èémí rẹ iná ni tí ó ń jó ọ run.

12. A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”

13. Ìwọ tí ó wà lọ́nà jínjìn, gbọ́ ohuntí mo ti ṣe;Ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!

14. Èrù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Ṣíhónì;ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́:“Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun?Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú ìjóná àìnípẹ̀kun?”

15. Ẹni tí ó ń rìn lódodotí ó ń sọ ohun tí ó tọ́,tí ó kọ èrè tí ó tibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá,tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí ó di etíi rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàntí ó sì di ojúu rẹ̀ sí àtipète ibi

16. ọkùnrin náà nìyìí tí yóò gbé ní ibi gíga,ẹni tí ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi.A ó máa mú àkàrà rẹ̀ wábẹ́ẹ̀ ni omi kì yóò wọ́n ọn.

17. Ojúu rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.

Ka pipe ipin Àìsáyà 33