Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 32:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wòó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodoàwọn olórí yóò máa ṣàkóso ní ìdájọ́.

2. Ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò dàbí ìdáàbòbò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì,gẹ́gẹ́ bí odò omi nínú aṣálẹ̀àti òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ òrùngbẹ.

3. Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní pàdé mọ́,àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.

4. Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè,àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.

5. A kò ní pe òmùgọ̀ ní bọ̀rọ̀kìnní mọ́tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún mọ̀dàrú.

6. Nítorí òmùgọ̀ ṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀,ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi:òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́runó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀;ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófoàti fún àwọn tí òrùngbẹ ń gbẹni ó mú omi kúrò.

7. Ìlànà àwọn aṣa jẹ ti ìkà,ó pète oríṣìí ìlànà ibiláti pa aláìní run pẹ̀lú irọ́bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ òtòsì sì tọ̀nà.

8. Ṣùgbọ́n bọ̀rọ̀kìnní ènìyàn a máa pète ohun ńláàti nípa èrò rere ni yóò dúró.

9. Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidiẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi,ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀,ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ!

10. Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kanẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì;ìkóórè àjàrà kò ní múnádóko,bẹ́ẹ̀ ni ìkóórè èṣo kò ní sí.

11. Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùnbẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀!Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò,ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ẹ yín.

12. Ẹ lu ọmú un yín fún pápá ìgbádùn náà,fún àwọn àjàrà eléso

Ka pipe ipin Àìsáyà 32