Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 3:4-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn,ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sìmáa jọba lóríi wọn.

5. Àwọn ènìyàn yóò sì má a pọ́nọmọnìkejì wọn lójúẹnìkan sí ẹnìkejìi rẹ̀, aládùúgbòsí aládùúgbò rẹ̀.Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbogun ti àwọn àgbà,àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí bọ̀rọ̀kìnní.

6. Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínu àwọnarákùnrin rẹ̀ múnínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé,“Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa,sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”

7. Ṣùgbọn ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé,“Èmi kò ní àtúnṣe kan.Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ò ní aṣọ nílé,ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.”

8. Jérúsálẹ́mù ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́nJúdà ń ṣubú lọ,ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa,láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.

9. Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn,wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sódómù;wọn ò fi pamọ́!Ègbé ni fún wọn!Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.

10. Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn,nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èṣo iṣẹ́ ẹ wọn.

11. Ẹ̀gbé ni fún aṣebi! Ìparun wà lóríi wọnA ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.

12. Àwọn ọ̀dọ̀mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójúàwọn obìnrin ń jọba lé wọn lórí.Áà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti sìyín lọ́nà,wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.

13. Olúwa bọ sí ipo rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.

14. Olúwa dojú ẹjọ́ kọàwọn alàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀.“Ẹyin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi,ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.

15. Kín ni èro yín láti máa run àwọnènìyàn mi túútúútí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ?”ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

16. Olúwa wí pé,“Àwọn obìnrin Ṣíónì jẹ́ agbéraga,wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn,tí wọn ń fojú pe ọkùnrin,tí wọn ń sọ̀dí bí wọn ti ń yan lọpẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjan wọnjan lọ́rùn ẹṣẹ̀ wọn.

17. Nítorí náà Olúwa yóò mú egbòwá sórí àwọn obìnrin Ṣíónì, Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.”

18. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti ìgbàrí àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá

Ka pipe ipin Àìsáyà 3