Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 29:17-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́a kò ní sọ Lẹ́bánónì di pápá ẹlẹ́tù lójúàti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí ihà?

18. Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà,láti inú fìrífìrí àti òkùnkùnni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.

19. Lẹ́ẹ̀kan síi àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa:àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì.

20. Aláìláàánú yóò pòórá,àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò dàwátì,gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀—

21. àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi,ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní kóòtùtí ẹ fi ẹ̀rí èkè dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.

22. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Ábúráhámù padà sọ sí ilé Jákọ́bù:“Ojú kì yóò ti Jákọ́bù mọ́;ojúu wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.

23. Nígbà tí wọ́n bá ríi láàrin àwọn ọmọ wọn,àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi,wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́,wọn yóò tẹ́wọ́gba mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jákọ́bùwọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

24. Gbogbo àwọn tí ń rìn ṣégeṣège ní ẹ̀mí yóò jèrè ìmọ̀;gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 29